Numeri 22:6
Numbers 22:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nísinsin yìí, wá fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí bú, nítorí wọ́n ní agbára jù fún mi. Nípa ṣíṣe èyí èmi ó ṣẹ́gun wọn, kí n sì lé wọn kúrò ní ilẹ̀ yìí. Nítorí tí mo mọ̀ pé ìbùkún ni fún àwọn tí ìwọ bá bùkún, ìfibú sì ni ẹni tí ìwọ bá fi bú.”
Numbers 22:6 in English
Numbers 22:6 · Berean Standard Bible
So please come now and put a curse on this people, because they are too mighty for me. Perhaps I may be able to defeat them and drive them out of the land; for I know that those you bless are blessed, and those you curse are cursed.”
Context
4Moabu sọ fún àwọn àgbàgbà Midiani pé, “Nísinsin yìí ni àwọn wọ̀nyí yóò lá gbogbo ohun tí ó yí wa ká, bí màlúù ṣe ń jẹ koríko tí ó wà nínú oko.”
Bẹ́ẹ̀ ni Balaki ọmọ Sippori, tí ó jẹ́ ọba Moabu nígbà náà, 5rán oníṣẹ́ pé Balaamu ọmọ Beori, tí ó wà ní Petori, ní ẹ̀bá odò Eufurate, ti ilẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ. Balaki sọ pé,
“Àwọn ènìyàn kan jáde wá láti Ejibiti; wọ́n bo gbogbo ilẹ̀ ayé wọ́n sì pa ibùdó súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi. 6Nísinsin yìí, wá fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí bú, nítorí wọ́n ní agbára jù fún mi. Nípa ṣíṣe èyí èmi ó ṣẹ́gun wọn, kí n sì lé wọn kúrò ní ilẹ̀ yìí. Nítorí tí mo mọ̀ pé ìbùkún ni fún àwọn tí ìwọ bá bùkún, ìfibú sì ni ẹni tí ìwọ bá fi bú.” 7Àti àwọn àgbàgbà Moabu àti Midiani sì lọ pẹ̀lú owó àyẹ̀wò lọ́nà wọn, nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Balaamu, wọ́n sọ nǹkan tí Balaki sọ fún wọn. 8“Ẹ sùn níbí lálẹ́ yìí,” Balaamu sọ fún un pé, “èmi ó padà wá fún un yín ní èsì nǹkan tí Olúwa bá wí fún mi.” Nítorí tí àwọn ìjòyè Moabu dúró sọ́dọ̀ rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.