Native Bible

Numbers 22:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

rán oníṣẹ́ pé Balaamu ọmọ Beori, tí ó wà ní Petori, ní ẹ̀bá odò Eufurate, ti ilẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ. Balaki sọ pé, “Àwọn ènìyàn kan jáde wá láti Ejibiti; wọ́n bo gbogbo ilẹ̀ ayé wọ́n sì pa ibùdó súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi.

Numbers 22:5 in English

Numbers 22:5 · Berean Standard Bible

he sent messengers to Balaam son of Beor at Pethor, which is by the Euphrates * in the land of his people. “Behold, a people has come out of Egypt,” said Balak. “They cover the face of the land and have settled next to me.

Context

3ẹ̀rù sì ba Moabu nítorí pé ọ̀pọ̀ ènìyàn wà níbẹ̀ nítòótọ́, Moabu kún fún ẹ̀rù nítorí àwọn ọmọ Israẹli. 4Moabu sọ fún àwọn àgbàgbà Midiani pé, “Nísinsin yìí ni àwọn wọ̀nyí yóò lá gbogbo ohun tí ó yí wa ká, bí màlúù ṣe ń jẹ koríko tí ó wà nínú oko.” Bẹ́ẹ̀ ni Balaki ọmọ Sippori, tí ó jẹ́ ọba Moabu nígbà náà, 5rán oníṣẹ́ pé Balaamu ọmọ Beori, tí ó wà ní Petori, ní ẹ̀bá odò Eufurate, ti ilẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ. Balaki sọ pé, “Àwọn ènìyàn kan jáde wá láti Ejibiti; wọ́n bo gbogbo ilẹ̀ ayé wọ́n sì pa ibùdó súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi. 6Nísinsin yìí, wá fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí bú, nítorí wọ́n ní agbára jù fún mi. Nípa ṣíṣe èyí èmi ó ṣẹ́gun wọn, kí n sì lé wọn kúrò ní ilẹ̀ yìí. Nítorí tí mo mọ̀ pé ìbùkún ni fún àwọn tí ìwọ bá bùkún, ìfibú sì ni ẹni tí ìwọ bá fi bú.” 7Àti àwọn àgbàgbà Moabu àti Midiani sì lọ pẹ̀lú owó àyẹ̀wò lọ́nà wọn, nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Balaamu, wọ́n sọ nǹkan tí Balaki sọ fún wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.