Native Bible

Numbers 22:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà angẹli Olúwa dúró ní ojú ọ̀nà tóóró láàrín ọgbà àjàrà, pẹ̀lú ògiri ní ọ̀nà méjèèjì.

Numbers 22:24 in English

Numbers 22:24 · Berean Standard Bible

Then the angel of the LORD stood in a narrow passage between two vineyards, with walls on either side.

Context

22Ṣùgbọ́n Ọlọ́run bínú gidigidi, angẹli Olúwa sì dúró lójú ọ̀nà láti dojú ìjà kọ ọ́. Balaamu ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ lọ, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ méjì sì wà pẹ̀lú rẹ̀. 23Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà sì rí angẹli Olúwa tí ó dúró ní ojú ọ̀nà pẹ̀lú idà tí a fàyọ ní ọwọ́ rẹ̀, ó kọjú kúrò ní ọ̀nà lọ sínú oko. Balaamu sì lù ú pé kí ó gbé òhun padà lọ sí ojú ọ̀nà. 24Nígbà náà angẹli Olúwa dúró ní ojú ọ̀nà tóóró láàrín ọgbà àjàrà, pẹ̀lú ògiri ní ọ̀nà méjèèjì. 25Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rí angẹli Olúwa, ó lẹ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ ògiri, ó sì rún ẹsẹ̀ Balaamu mọ́ ògiri. Nígbà náà, ó tún nà án, lẹ́ẹ̀kan sí i. 26Nígbà náà angẹli Olúwa súnmọ́ wájú ó sì dúró níbi ọ̀nà tóóró níbi tí kò ti sí ọ̀nà láti yípadà, bóyá ní ọ̀tún tàbí òsì.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.