Numeri 22:23
Numbers 22:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà sì rí angẹli Olúwa tí ó dúró ní ojú ọ̀nà pẹ̀lú idà tí a fàyọ ní ọwọ́ rẹ̀, ó kọjú kúrò ní ọ̀nà lọ sínú oko. Balaamu sì lù ú pé kí ó gbé òhun padà lọ sí ojú ọ̀nà.
Numbers 22:23 in English
Numbers 22:23 · Berean Standard Bible
When the donkey saw the angel of the LORD standing in the road with a drawn sword in his hand, she turned off the path and went into a field. So Balaam beat her to return her to the path.
Context
21Balaamu dìde ní òwúrọ̀, ó sì di ẹrù lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ òun pẹ̀lú àwọn ìjòyè Moabu. 22Ṣùgbọ́n Ọlọ́run bínú gidigidi, angẹli Olúwa sì dúró lójú ọ̀nà láti dojú ìjà kọ ọ́. Balaamu ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ lọ, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ méjì sì wà pẹ̀lú rẹ̀. 23Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà sì rí angẹli Olúwa tí ó dúró ní ojú ọ̀nà pẹ̀lú idà tí a fàyọ ní ọwọ́ rẹ̀, ó kọjú kúrò ní ọ̀nà lọ sínú oko. Balaamu sì lù ú pé kí ó gbé òhun padà lọ sí ojú ọ̀nà. 24Nígbà náà angẹli Olúwa dúró ní ojú ọ̀nà tóóró láàrín ọgbà àjàrà, pẹ̀lú ògiri ní ọ̀nà méjèèjì. 25Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rí angẹli Olúwa, ó lẹ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ ògiri, ó sì rún ẹsẹ̀ Balaamu mọ́ ògiri. Nígbà náà, ó tún nà án, lẹ́ẹ̀kan sí i.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.