Numeri 21:2
Numbers 21:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Israẹli jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa pé, “Bí o bá lè fi àwọn ènìyàn yìí lé wa lọ́wọ́, gbogbo ìlú wọn ni a ó parun.”
Numbers 21:2 in English
Numbers 21:2 · Berean Standard Bible
So Israel made a vow to the LORD: “If You will deliver this people into our hands, we will devote their cities to destruction.*”
Context
1Nígbà tí ọba Aradi ará Kenaani, tí ń gbé ní gúúsù gbọ́ wí pé Israẹli ń bọ̀ wá ní ojú ọ̀nà Atarimu, ó bá Israẹli jà ó sì fi agbára mú díẹ̀ lára wọn. 2Nígbà náà ni Israẹli jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa pé, “Bí o bá lè fi àwọn ènìyàn yìí lé wa lọ́wọ́, gbogbo ìlú wọn ni a ó parun.” 3Olúwa gbọ́ ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli, ó sì fi àwọn ará Kenaani lé wọn lọ́wọ́. Wọ́n pa wọ́n run pátápátá; torí náà ni a ṣe ń pe ibẹ̀ ní Horma. 4Wọ́n rin ìrìnàjò láti òkè Hori lọ sí ọ̀nà tó lọ sí Òkun Pupa, láti kọjá yípo Edomu. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn bínú ní ojú ọ̀nà;
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.