Numeri 21:14
Numbers 21:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìdí nìyìí tí ìwé ogun Olúwa se wí pé, “…Wahebu ní Sufa, Òkun Pupa àti ní odò Arnoni
Numbers 21:14 in English
Numbers 21:14 · Berean Standard Bible
Therefore it is stated in the Book of the Wars of the LORD: “Waheb in Suphah and the wadis of the Arnon,
Context
12Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti gbéra wọ́n sì pa ibùdó ní àfonífojì Seredi. 13Láti ibẹ̀ lọ, wọn ṣí, wọ́n sì dó sí ìhà kejì Arnoni, tí ó wà ní aginjù tí ó wà ní agbègbè ilẹ̀ àwọn ọmọ Amori. Arnoni jẹ́ ààlà fún ilẹ̀ Moabu, láàrín Moabu àti Amori. 14Ìdí nìyìí tí ìwé ogun Olúwa se wí pé,
“…Wahebu ní Sufa, Òkun Pupa àti
ní odò Arnoni 15àti ní ìṣàn odò
tí ó darí sí ibùjókòó Ari
tí ó sì fi ara ti ìpínlẹ̀ Moabu.” 16Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ rìn dé Beeri, èyí ni kànga tí Olúwa sọ fún Mose, “Kó àwọn ènìyàn jọ èmi ó sì fún wọn ní omi.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.