Numeri 18:27
Numbers 18:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
A ó ka ọrẹ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọkà irúgbìn láti ilẹ̀ ìpakà tàbí wáìnì láti fún wa.
Numbers 18:27 in English
Numbers 18:27 · Berean Standard Bible
Your offering will be reckoned to you as grain from the threshing floor or juice from the winepress.
Context
25Olúwa sọ fún Mose pé, 26“Sọ fún àwọn ọmọ Lefi kí o sì wí fún wọn pé: ‘Nígbà tí ìdámẹ́wàá bá ń wọlé láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ. O gbọdọ̀ mú ìdámẹ́wàá lára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ Olúwa. 27A ó ka ọrẹ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọkà irúgbìn láti ilẹ̀ ìpakà tàbí wáìnì láti fún wa. 28Báyìí ni ìwọ gan an náà yóò mú ọrẹ wa fún Olúwa láti ara ìdámẹ́wàá tí ìwọ gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli. Láti ara ìdámẹ́wàá ó gbọdọ̀ mú ọrẹ Olúwa fún Aaroni àlùfáà. 29Ìwọ gbọdọ̀ mú wá gẹ́gẹ́ bí ìpín Olúwa èyí tí ó dára jùlọ àti tí ó jẹ́ mímọ́ jùlọ lára gbogbo nǹkan tí wọ́n mú wá fún ọ.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.