Numeri 17:10
Numbers 17:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú ọ̀pá Aaroni padà wá síwájú ẹ̀rí, láti fi pamọ́ gẹ́gẹ́ bí àmì fún àwọn ọlọ̀tẹ̀. Èyí ó sì mú òpin bá kíkùn sínú wọn sí mi, kí wọn kí ó má ba à kú.”
Numbers 17:10 in English
Numbers 17:10 · Berean Standard Bible
The LORD said to Moses, “Put Aaron’s staff back in front of the Testimony, to be kept as a sign for the rebellious, so that you may put an end to their grumbling against Me, lest they die.”
Context
8Ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì Mose wọ inú àgọ́ ẹ̀rí lọ, ó sì rí ọ̀pá Aaroni, tí ó dúró fún ẹ̀yà Lefi, kì í ṣe wí pé ó hù nìkan, ṣùgbọ́n ó rúwé, ó yọ ìtànná, ó sì so èso almondi. 9Nígbà náà ni Mose kó gbogbo àwọn ọ̀pá jáde láti iwájú Olúwa wá fún àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n wò wọ́n, ẹnìkọ̀ọ̀kan sì mú ọ̀pá tirẹ̀. 10Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú ọ̀pá Aaroni padà wá síwájú ẹ̀rí, láti fi pamọ́ gẹ́gẹ́ bí àmì fún àwọn ọlọ̀tẹ̀. Èyí ó sì mú òpin bá kíkùn sínú wọn sí mi, kí wọn kí ó má ba à kú.” 11Mose sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti páláṣẹ fún un. 12Àwọn ọmọ Israẹli sọ fún Mose pé, “Àwa yóò kú! A ti sọnù, gbogbo wa ti sọnù!
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.