Numeri 16:48
Numbers 16:48 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó dúró láàrín àwọn alààyè àti òkú, àjàkálẹ̀-ààrùn náà sì dúró.
Numbers 16:48 in English
Numbers 16:48 · Berean Standard Bible
He stood between the living and the dead, and the plague was halted.
Context
46Mose sì sọ fún Aaroni pé, “Mú àwo tùràrí, kí o fi iná sí i lórí pẹpẹ, fi tùràrí sínú rẹ̀, kí o sì tètè mu lọ sí àárín ìjọ ènìyàn láti ṣe ètùtù fún wọn nítorí pé ìbínú Olúwa ti jáde, àjàkálẹ̀-ààrùn sì ti bẹ̀rẹ̀.” 47Aaroni ṣe bí Mose ti wí, ó sáré lọ sí àárín àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n àjàkálẹ̀-ààrùn ti bẹ̀rẹ̀ láàrín wọn, ṣùgbọ́n Aaroni fín tùràrí, ó sì ṣe ètùtù fún wọn. 48Ó dúró láàrín àwọn alààyè àti òkú, àjàkálẹ̀-ààrùn náà sì dúró. 49Ṣùgbọ́n àjàkálẹ̀-ààrùn ti pa ẹgbàá méje ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (14,700) ènìyàn ní àfikún sí àwọn tí ó kú níbi ìṣẹ̀lẹ̀ Kora. 50Aaroni padà tọ Mose lọ ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé nítorí pé àjàkálẹ̀-ààrùn náà ti dúró.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.