Numeri 15:23
Numbers 15:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
èyí ni gbogbo òfin tí Olúwa fún yín láti ẹnu Mose láti ọjọ́ tí Olúwa ti fún yín àti títí dé ìran tó ń bọ̀.
Numbers 15:23 in English
Numbers 15:23 · Berean Standard Bible
all that the LORD has commanded you through Moses from the day the LORD gave them and continuing through the generations to come—
Context
21Nínú àkọ́so oúnjẹ yín ni kí ẹ ti máa mú ọrẹ ìgbésókè yìí fún Olúwa. 22“ ‘Bí ẹ bá kùnà láìròtẹ́lẹ̀ láti pa àwọn òfin tí Olúwa fún Mose mọ́, 23èyí ni gbogbo òfin tí Olúwa fún yín láti ẹnu Mose láti ọjọ́ tí Olúwa ti fún yín àti títí dé ìran tó ń bọ̀. 24Bí ẹ̀ṣẹ̀ bá wáyé láìròtẹ́lẹ̀ láìjẹ́ pé ìjọ ènìyàn mọ̀ sí i, nígbà náà ni kí gbogbo ìjọ ènìyàn mú ọ̀dọ́ akọ màlúù kan wá fún ẹbọ sísun bí òórùn dídùn sí Olúwa, pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun mímu rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà, pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. 25Àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù, fun gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli, a ó sì dáríjì wọ́n, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àìròtẹ́lẹ̀, wọ́n sì ti mú ọrẹ àfinásun wá fún Olúwa nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.