Numeri 14:11
Numbers 14:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa sọ fún Mose pé, “Fún ìgbà wo ni àwọn ènìyàn yìí yóò ti kẹ́gàn mi tó? Báwo ni yóò ti pẹ́ tó tí wọ́n ó fi kọ̀ jálẹ̀ láti gbà mí gbọ́, pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ àmì tí mo ṣe láàrín wọn?
Numbers 14:11 in English
Numbers 14:11 · Berean Standard Bible
And the LORD said to Moses, “How long will this people treat Me with contempt? How long will they refuse to believe in Me, despite all the signs I have performed among them?
Context
9Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa. Kí ẹ sì má bẹ̀rù àwọn ènìyàn ìlú náà, nítorí pé a ó gbé wọn mì, ààbò wọn ti fi wọ́n sílẹ̀, Olúwa sì wà pẹ̀lú àwa, ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn.” 10Ṣùgbọ́n gbogbo ìjọ ènìyàn sì ń sọ pé àwọn yóò sọ wọ́n lókùúta pa. Nígbà náà ni ògo Olúwa fi ara hàn ní àgọ́ ìpàdé níwájú àwọn ọmọ Israẹli. 11Olúwa sọ fún Mose pé, “Fún ìgbà wo ni àwọn ènìyàn yìí yóò ti kẹ́gàn mi tó? Báwo ni yóò ti pẹ́ tó tí wọ́n ó fi kọ̀ jálẹ̀ láti gbà mí gbọ́, pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ àmì tí mo ṣe láàrín wọn? 12Èmi ó kọlù wọ́n pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn, èmi ó gba ogún wọn lọ́wọ́ wọn, èmi ó sì pa wọ́n run ṣùgbọ́n èmi ó sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá tó sì lágbára jù wọ́n lọ.” 13Ṣùgbọ́n Mose sọ fún Olúwa pé, “Nígbà náà ni àwọn ará Ejibiti yóò gbọ́! Nítorí pé nípa agbára rẹ ni ìwọ fi mú àwọn ènìyàn wọ̀nyí jáde kúrò láàrín wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.