Native Bible

Numbers 13:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí wọ́n dé àfonífojì Eṣkolu, wọ́n gé ẹ̀ka kan tó ní ìdì èso àjàrà gireepu kan. Àwọn méjì sì fi ọ̀pá kan gbé e; wọ́n tún mú èso pomegiranate àti èso ọ̀pọ̀tọ́ pẹ̀lú.

Numbers 13:23 in English

Numbers 13:23 · Berean Standard Bible

When they came to the Valley of Eshcol,* they cut down a branch with a single cluster of grapes, which they carried on a pole between two men. They also took some pomegranates and figs.

Context

21Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gòkè lọ láti yẹ ilẹ̀ náà wò, wọ́n lọ láti aginjù Sini títí dé Rehobu lọ́nà Lebo-Hamati. 22Wọ́n gba gúúsù lọ sí Hebroni níbi tí Ahimani, Ṣeṣai àti Talmai tí í ṣe irú-ọmọ Anaki ń gbé. (A ti kọ́ Hebroni ní ọdún méje ṣáájú Ṣoani ní Ejibiti.) 23Nígbà tí wọ́n dé àfonífojì Eṣkolu, wọ́n gé ẹ̀ka kan tó ní ìdì èso àjàrà gireepu kan. Àwọn méjì sì fi ọ̀pá kan gbé e; wọ́n tún mú èso pomegiranate àti èso ọ̀pọ̀tọ́ pẹ̀lú. 24Wọ́n sì sọ ibẹ̀ ní àfonífojì Eṣkolu nítorí ìdì èso gireepu tí àwọn ọmọ Israẹli gé níbẹ̀. 25Wọ́n padà sílé lẹ́yìn ogójì ọjọ́ tí wọ́n ti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.