Numeri 12:13
Numbers 12:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Torí èyí Mose sì kígbe sí Olúwa, “Ọlọ́run, jọ̀wọ́, mú un láradá!”
Numbers 12:13 in English
Numbers 12:13 · Berean Standard Bible
So Moses cried out to the LORD, “O God, please heal her!”
Context
11Aaroni sì wí fún Mose pé, “Jọ̀wọ́ olúwa mi, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀, èyí tí a fi ìwà òmùgọ̀ dá sí wa lọ́rùn. 12Má ṣe jẹ́ kí ó dàbí òkú ọmọ tí a bí, tí ìdajì ara rẹ̀ ti rà dànù.” 13Torí èyí Mose sì kígbe sí Olúwa, “Ọlọ́run, jọ̀wọ́, mú un láradá!” 14Olúwa sì dá Mose lóhùn, “Bí baba rẹ̀ bá tutọ́ sí i lójú, ojú kò wa ní í tì í fún ọjọ́ méje? Dá a dúró sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ méje, lẹ́yìn èyí ki a tó ó le mú wọlé.” 15Miriamu sì dúró sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ méje, àwọn ènìyàn kò sì tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò wọn títí tí Miriamu fi wọ inú ibùdó padà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.