Native Bible

Numbers 10:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ó bá jẹ́ ọ̀kan ni o fọn, nígbà náà ni àwọn olórí ẹ̀yà Israẹli yóò péjọ síwájú rẹ.

Numbers 10:4 in English

Numbers 10:4 · Berean Standard Bible

But if only one is sounded, then the leaders, the heads of the clans of Israel, are to gather before you.

Context

2“Ṣe fèrè fàdákà méjì pẹ̀lú fàdákà lílù, kí o máa lò ó láti máa fi pe ìjọ ènìyàn àti láti máa fi darí ìrìnàjò lọ sí ibùdó yín. 3Nígbà tí o bá fọn méjèèjì gbogbo ìjọ ènìyàn yóò pé síwájú rẹ ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 4Bí ó bá jẹ́ ọ̀kan ni o fọn, nígbà náà ni àwọn olórí ẹ̀yà Israẹli yóò péjọ síwájú rẹ. 5Nígbà tí o bá fun ìpè ìdágìrì, àwọn ẹ̀yà tó pa ibùdó sí ìhà ìlà-oòrùn ni yóò gbéra. 6Nígbà tí o bá fun ìpè ìdágìrì kejì, ibùdó tó wà ní ìhà gúúsù ni yóò gbéra. Ìpè ìdágìrì yìí ni yóò jẹ́ àmì fún gbígbéra.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.