Nehemiah 9:22
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ìwọ fi àwọn ìjọba àti àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ náà fún wọ́n. Wọ́n sì gba ilẹ̀ ọba Sihoni ará a Heṣboni àti ilẹ̀ Ogu ọba Baṣani.
Nehemiah 9:22 in English
Nehemiah 9:22 · Berean Standard Bible
You gave them kingdoms and peoples and allotted to them every corner of the land. So they took the land of Sihon * king of Heshbon and of Og king of Bashan.
Context
20Ìwọ fi ẹ̀mí rere rẹ fún wọn láti kọ́ wọn. Ìwọ kò dá manna rẹ dúró ní ẹnu wọn, ó sì fún wọn ní omi fún òǹgbẹ. 21Fún ogójì ọdún ni ìwọ fi bọ́ wọn ní aginjù; wọn kò ṣe aláìní ohunkóhun, aṣọ wọn kò gbó bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ wọn kò wú. 22“Ìwọ fi àwọn ìjọba àti àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ náà fún wọ́n. Wọ́n sì gba ilẹ̀ ọba Sihoni ará a Heṣboni àti ilẹ̀ Ogu ọba Baṣani. 23Ìwọ ti mú àwọn ọmọ wọn pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ó sì mú wọn wá sí ilẹ̀ tí o ti sọ fún àwọn baba wọn pé kí wọn wọ̀, kí wọn sì jogún un rẹ̀. 24Àwọn ọkùnrin wọn wọ inú rẹ̀, wọ́n sì gbà ilẹ̀ náà. Ìwọ sì tẹ orí àwọn ará a Kenaani, tí ń gbé inú ilẹ̀ náà ba níwájú wọn; ó fi àwọn ará a Kenaani lé wọn lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ọba wọn àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà kí wọn ṣe wọn bí ó ti wù wọ́n.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.