Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n kọ̀ láti fetísílẹ̀, wọ́n sì kùnà láti rántí iṣẹ́ ìyanu tí ìwọ ṣe ní àárín wọn. Wọ́n ṣe agídí, nínú ìṣọ̀tẹ̀ wọn, wọ́n yan olórí láti padà sí oko ẹrú wọn. Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run tí ó ń dáríjì, olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú, ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́. Nítorí náà ìwọ kò sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀,

Nehemiah 9:17 in English

Nehemiah 9:17 · Berean Standard Bible

They refused to listen and failed to remember the wonders You performed among them. They stiffened their necks and appointed a leader to return them to their bondage in Egypt.* But You are a forgiving God, gracious and compassionate, slow to anger and rich in loving devotion, and You did not forsake them.

Context

15Ìwọ fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run wá nígbà tí ebi ń pa wọ́n àti nígbà òǹgbẹ, o fún wọn ní omi láti inú àpáta; o sì sọ fún wọn pé, kí wọ́n lọ láti lọ gba ilẹ̀ náà tí ìwọ ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti fi fún wọn nípa ìgbọ́wọ́sókè. 16“Ṣùgbọ́n àwọn, baba ńlá wa, wọ́n ṣe ìgbéraga, wọ́n sì ṣe agídí, wọn kò sì tẹríba fún àwọn ìlànà rẹ. 17Wọ́n kọ̀ láti fetísílẹ̀, wọ́n sì kùnà láti rántí iṣẹ́ ìyanu tí ìwọ ṣe ní àárín wọn. Wọ́n ṣe agídí, nínú ìṣọ̀tẹ̀ wọn, wọ́n yan olórí láti padà sí oko ẹrú wọn. Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run tí ó ń dáríjì, olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú, ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́. Nítorí náà ìwọ kò sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀, 18nítòótọ́ nígbà tí wọ́n ṣe ẹgbọrọ màlúù dídá, tí wọ́n sì wí pé, ‘Èyí ni Ọlọ́run rẹ tí ó mú ọ gòkè láti Ejibiti wá; tàbí nígbà tí wọ́n sọ ọ̀rọ̀-òdì tí ó burú jàì’. 19“Nítorí àánú ńlá rẹ, ìwọ kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ní aginjù. Ní ọ̀sán ọ̀wọn ìkùùkuu kò kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn láti ṣe amọ̀nà an wọn, tàbí ọ̀wọ́n iná láti tàn sí wọn ní òru ní ọ̀nà tí wọn yóò rìn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.