Nehemiah 8:5
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Esra ṣí ìwé náà, gbogbo ènìyàn sì le rí í nítorí ó dúró níbi tí ó ga ju gbogbo ènìyàn lọ; bí ó sì ti ṣí ìwé náà, gbogbo ènìyàn dìde dúró.
Nehemiah 8:5 in English
Nehemiah 8:5 · Berean Standard Bible
Ezra opened the book in full view of all the people, since he was standing above them all, and as he opened it, all the people stood up.
Context
3Ó kà á sókè láti òwúrọ̀ títí di ọ̀sán bí ó ti kọjú sí ìta ní iwájú ibodè omi ní ojú u gbogbo ọkùnrin, obìnrin àti àwọn ènìyàn tókù tí òye le è yé tí wọ́n wà níbẹ̀. Gbogbo ènìyàn sì fetísílẹ̀ sí ìwé òfin náà pẹ̀lú ìfarabalẹ̀. 4Akọ̀wé Esra dìde dúró lórí i pẹpẹ ìdúrólé tí a fi igi kàn fún ètò yìí. Ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ọ̀tún ni Mattitiah, Ṣema, Anaiah, Uriah, Hilkiah àti Maaseiah gbé dúró sí, ní ẹ̀gbẹ́ òsì rẹ̀ ní Pedaiah, Misaeli, Malkiah, Haṣumu, Haṣabadana, Sekariah àti Meṣullamu dúró sí. 5Esra ṣí ìwé náà, gbogbo ènìyàn sì le rí í nítorí ó dúró níbi tí ó ga ju gbogbo ènìyàn lọ; bí ó sì ti ṣí ìwé náà, gbogbo ènìyàn dìde dúró. 6Esra yin Olúwa, Ọlọ́run alágbára; gbogbo ènìyàn gbé ọwọ́ wọn sókè, wọ́n sì wí pé, “Àmín! Àmín!” Nígbà náà ni wọ́n wólẹ̀ wọ́n sì sin Olúwa ní ìdojúbolẹ̀. 7Àwọn Lefi—Jeṣua, Bani, Ṣerebiah, Jamini, Akkubu, Ṣabbetai, Hodiah, Maaseiah, Kelita, Asariah, Josabadi, Hanani àti Pelaiah—kọ́ wọn ni òfin náà bí àwọn ènìyàn ṣe wà ní ìdúró síbẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.