Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Síwájú sí í, láti ogún ọdún ọba Artasasta, nígbà tí a ti yàn mí láti jẹ́ baálẹ̀ wọn ní ilẹ̀ Juda, títí di ọdún kejìlélọ́gbọ̀n ìjọba rẹ̀—ọdún méjìlá, èmi àti àwọn arákùnrin mi kò jẹ oúnjẹ baálẹ̀.

Nehemiah 5:14 in English

Nehemiah 5:14 · Berean Standard Bible

Furthermore, from the day King Artaxerxes appointed me to be their governor in the land of Judah, from his twentieth year until his thirty-second year (twelve years total), neither I nor my brothers ate the food allotted to the governor.

Context

12Wọ́n wí pé, “Àwa yóò dá a padà. Àwa kì yóò sì béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ wọn mọ́. Àwa yóò ṣe bí o ti wí.” Nígbà náà mo pe àwọn àlùfáà, mo sì mú kí àwọn ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè búra láti jẹ́ kí wọ́n ṣe ohun tí wọ́n ti ṣe ìlérí. 13Mo sì gbọn ìṣẹ́tí aṣọ mi, mo wí pé, “Báyìí ni kí Ọlọ́run gbọn olúkúlùkù ènìyàn tí kò bá pa ìlérí yìí mọ́ jáde kúrò ní ilẹ̀ ìní i rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni kí a gbọn irú ẹni bẹ́ẹ̀ jáde kí ó sì ṣófo!” Gbogbo ìjọ ènìyàn sì wí pé, “Àmín,” wọ́n sì fi ìyìn fún Olúwa. Àwọn ènìyàn náà sì ṣe bí wọ́n ti ṣe ìlérí. 14Síwájú sí í, láti ogún ọdún ọba Artasasta, nígbà tí a ti yàn mí láti jẹ́ baálẹ̀ wọn ní ilẹ̀ Juda, títí di ọdún kejìlélọ́gbọ̀n ìjọba rẹ̀—ọdún méjìlá, èmi àti àwọn arákùnrin mi kò jẹ oúnjẹ baálẹ̀. 15Ṣùgbọ́n àwọn baálẹ̀ ìṣáájú—tí ó ti wà ṣáájú mi—gbe àjàgà wúwo lé àwọn ènìyàn lórí yàtọ̀ fún oúnjẹ àti wáìnì wọ́n sì tún gba ogójì ṣékélì fàdákà lọ́wọ́ wọn. Kódà àwọn ìránṣẹ́ wọn tún jẹ gàba lórí wọn. Ṣùgbọ́n èmi kò ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ìbẹ̀rù Ọlọ́run. 16Dípò bẹ́ẹ̀, mo fi ara mi jì fún iṣẹ́ lórí odi yìí. Gbogbo àwọn ènìyàn mi péjọ síbẹ̀ fún iṣẹ́ náà; a kò sì gba ilẹ̀ kankan.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.