Nehemiah 4:22
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ìgbà náà mo tún sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn àti olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ dúró ní Jerusalẹmu ní òru, nítorí kí wọn le jẹ́ ẹ̀ṣọ́ fún wa ní òru, kí wọn sì le ṣe iṣẹ́ ní ọ̀sán.”
Nehemiah 4:22 in English
Nehemiah 4:22 · Berean Standard Bible
At that time I also said to the people, “Let every man and his servant spend the night inside Jerusalem, so that they can stand guard by night and work by day.”
Context
20Níbikíbi tí ẹ bá ti gbọ́ ohùn ìpè, ẹ da ara pọ̀ mọ́ wa níbẹ̀. Ọlọ́run wa yóò jà fún wa!” 21Bẹ́ẹ̀ ni àwa ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú àwọn ìdajì ènìyàn tí ó di ọ̀kọ̀ mú, láti òwúrọ̀ kùtùkùtù títí di ìgbà tí ìràwọ̀ yóò fi yọ. 22Ní ìgbà náà mo tún sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn àti olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ dúró ní Jerusalẹmu ní òru, nítorí kí wọn le jẹ́ ẹ̀ṣọ́ fún wa ní òru, kí wọn sì le ṣe iṣẹ́ ní ọ̀sán.” 23Bẹ́ẹ̀ ni èmi àti àwọn arákùnrin mi àti àwọn ènìyàn mi àti àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ó wà pẹ̀lú mi kò bọ́ aṣọ wa, olúkúlùkù wa ní ohun ìjà tirẹ̀, kódà nígbà tí wọ́n bá ń lọ pọn omi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.