Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Níbikíbi tí ẹ bá ti gbọ́ ohùn ìpè, ẹ da ara pọ̀ mọ́ wa níbẹ̀. Ọlọ́run wa yóò jà fún wa!”

Nehemiah 4:20 in English

Nehemiah 4:20 · Berean Standard Bible

Wherever you hear the sound of the horn, rally to us there. Our God will fight for us!”

Context

18olúkúlùkù àwọn ọ̀mọ̀lé fi idà wọn sí ẹ̀gbẹ́ wọn bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ń fọn ìpè dúró pẹ̀lú mi. 19Nígbà náà ni mo sọ fún àwọn ọlọ́lá, àwọn ìjòyè àti àwọn ènìyàn tókù pé, “Iṣẹ́ náà fẹ̀ ó sì pọ̀, a sì ti jìnnà sí ara wa púpọ̀ lórí odi. 20Níbikíbi tí ẹ bá ti gbọ́ ohùn ìpè, ẹ da ara pọ̀ mọ́ wa níbẹ̀. Ọlọ́run wa yóò jà fún wa!” 21Bẹ́ẹ̀ ni àwa ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú àwọn ìdajì ènìyàn tí ó di ọ̀kọ̀ mú, láti òwúrọ̀ kùtùkùtù títí di ìgbà tí ìràwọ̀ yóò fi yọ. 22Ní ìgbà náà mo tún sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn àti olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ dúró ní Jerusalẹmu ní òru, nítorí kí wọn le jẹ́ ẹ̀ṣọ́ fún wa ní òru, kí wọn sì le ṣe iṣẹ́ ní ọ̀sán.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.