Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́yìn in rẹ̀ ni, Nehemiah ọmọ Asbuku, alákòóso ìdajì agbègbè Beti-Suri ṣe àtúnmọ dé ibi ọ̀ọ́kán òdìkejì ibojì Dafidi, títí dé adágún omi àtọwọ́dá àti títí dé ilé àwọn alágbára.

Nehemiah 3:16 in English

Nehemiah 3:16 · Berean Standard Bible

Beyond him, Nehemiah son of Azbuk, ruler of a half-district of Beth-zur, made repairs up to a point opposite the tombs of David, as far as the artificial pool and the House of the Mighty.

Context

14Ẹnu ibodè Ààtàn ni Malkiah ọmọ Rekabu, alákòóso agbègbè Beti-Hakeremu tún mọ. Ó tún un mọ, ó sì gbé àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, àwọn ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn ìdè rẹ̀ sí ààyè wọn. 15Ẹnu ibodè orísun ni Ṣalluni Koli-Hose, alákòóso agbègbè Mispa tún mọ. Ó tún ún mọ, ó kan òrùlé e rẹ̀ yíká, ó gbé àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ àwọn ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn idẹ rẹ̀ ró sí ààyè wọn. Ó tún tún odi adágún Siloamu mọ, ní ẹ̀gbẹ́ ọgbà ọba, títí dé àwọn àtẹ̀gùn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ láti ìlú Dafidi. 16Lẹ́yìn in rẹ̀ ni, Nehemiah ọmọ Asbuku, alákòóso ìdajì agbègbè Beti-Suri ṣe àtúnmọ dé ibi ọ̀ọ́kán òdìkejì ibojì Dafidi, títí dé adágún omi àtọwọ́dá àti títí dé ilé àwọn alágbára. 17Lẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn ará a Lefi, ní abẹ́ ẹ Rehumu ọmọ Bani. Lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ni Haṣabiah, alákòóso ìdajì agbègbè Keila ṣe àtúnṣe fún agbègbè tirẹ̀. 18Lẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn Lefi arákùnrin wọn ní abẹ́ àkóso Binnui ṣe àtúnṣe, Bafai ọmọ Henadadi, ìjòyè àwọn ìdajì agbègbè Keila.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.