Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mo sì lọ sí Jerusalẹmu, lẹ́yìn ìgbà tí mo dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta.

Nehemiah 2:11 in English

Nehemiah 2:11 · Berean Standard Bible

After I had arrived in Jerusalem and had been there three days,

Context

9Bẹ́ẹ̀ ni mo lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn baálẹ̀ agbègbè Eufurate, mo sì fún wọn ní àwọn lẹ́tà ọba. Ọba sì ti rán àwọn ológun àti àwọn ẹlẹ́ṣin ogun pẹ̀lú mi. 10Nígbà tí Sanballati ará Horoni àti Tobiah ará a Ammoni tí wọ́n jẹ́ ìjòyè gbọ́ nípa èyí pé, ẹnìkan wá láti mú ìtẹ̀síwájú bá àlàáfíà àwọn ará Israẹli inú bí wọn gidigidi. 11Mo sì lọ sí Jerusalẹmu, lẹ́yìn ìgbà tí mo dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta. 12Mo jáde ní òru pẹ̀lú àwọn ọkùnrin díẹ̀. Èmi kò sì sọ fún ẹnìkankan ohun tí Ọlọ́run mi ti fi sí ọkàn mi láti ṣe fún Jerusalẹmu. Kò sí ẹranko kankan pẹ̀lú mi, bí kò ṣe ọ̀kan ṣoṣo tí mo gùn. 13Ní òru, mo jáde lọ sí àfonífojì ibodè sí ìhà kànga Jakali àti sí ẹnu ibodè Ààtàn àti ẹnu ibodè rẹ̀ èyí tí ó ti wó odi Jerusalẹmu tí ó lulẹ̀, tí a ti fi iná sun.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.