Nehemiah 13:28
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọ̀kan lára àwọn ọmọ Joiada, ọmọ Eliaṣibu olórí àlùfáà jẹ́ àna Sanballati ará a Horoni. Mo sì lé e jáde kúrò lọ́dọ̀ mi.
Nehemiah 13:28 in English
Nehemiah 13:28 · Berean Standard Bible
Even one of the sons of Jehoiada son of Eliashib the high priest had become a son-in-law to Sanballat the Horonite. Therefore I drove him away from me.
Context
26Kì í ha á ṣe àwọn ìgbéyàwó bí irú èyí ni ọba Solomoni fi dá ẹ̀ṣẹ̀? Láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, kò sí ọba kan bí i tirẹ̀. Ọlọ́run rẹ̀ fẹ́ràn rẹ̀, Ọlọ́run sì fi jẹ ọba lórí i gbogbo Israẹli, ṣùgbọ́n àwọn obìnrin àjèjì ti sọ ọ́ sínú òfin ẹ̀ṣẹ̀. 27Ǹjẹ́ ó ha yẹ kí àwa tún gbọ́ báyìí pé ẹ̀yin náà tún ń ṣe àwọn nǹkan tí ó burú jọjọ wọ̀nyí tí ẹ sì ń ṣe aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wa nípa fífẹ́ àwọn obìnrin àjèjì?” 28Ọ̀kan lára àwọn ọmọ Joiada, ọmọ Eliaṣibu olórí àlùfáà jẹ́ àna Sanballati ará a Horoni. Mo sì lé e jáde kúrò lọ́dọ̀ mi. 29Rántí wọn, Ọlọ́run mi, nítorí wọ́n ti ba iṣẹ́ àlùfáà jẹ́ pẹ̀lú májẹ̀mú iṣẹ́ àlùfáà àti ti àwọn Lefi. 30Nítorí náà, mo ya àwọn àlùfáà àti àwọn Lefi sí mímọ́ kúrò nínú gbogbo ohun àjèjì, mo sì yan iṣẹ́ fún wọn, olúkúlùkù sí ẹnu iṣẹ́ rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.