Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Láti inú àwọn ọmọ Lefi: Ṣemaiah ọmọ Haṣubu, ọmọ Asrikamu, ọmọ Haṣabiah ọmọ Bunni;

Nehemiah 11:15 in English

Nehemiah 11:15 · Berean Standard Bible

From the Levites: Shemaiah son of Hasshub, the son of Azrikam, the son of Hashabiah, the son of Bunni;

Context

13àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olórí ìdílé jẹ́ òjìlúgba ó lé méjì (242) ọkùnrin: Amaṣai ọmọ Asareeli, ọmọ Ahsai, ọmọ Meṣilemoti, ọmọ Immeri, 14àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ alágbára ọkùnrin jẹ́ méjìdínláàádóje (128). Olórí òṣìṣẹ́ ẹ wọn ni Sabdieli ọmọ Hagedolimu. 15Láti inú àwọn ọmọ Lefi: Ṣemaiah ọmọ Haṣubu, ọmọ Asrikamu, ọmọ Haṣabiah ọmọ Bunni; 16Ṣabbetai àti Josabadi, olórí méjì nínú àwọn ọmọ Lefi, àwọn tí ó jẹ́ alábojútó iṣẹ́ tí ó wà ní ẹ̀yìn àgbàlá ilé Ọlọ́run; 17Mattaniah ọmọ Mika, ọmọ Sabdi, ọmọ Asafu, adarí tí ó ń ṣáájú ìdúpẹ́ àti àdúrà; Bakbukiah ẹnìkejì láàrín àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀; àti Abida ọmọ Ṣammua, ọmọ Galali, ọmọ Jedutuni.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.