Marku 8:32
Mark 8:32 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jesu bá wọn sọ̀rọ̀ yìí, láìfi ohunkóhun pamọ́ fún wọn, ṣùgbọ́n Peteru pe Jesu sẹ́yìn, ó sì bẹ̀rẹ̀ si bá a wí.
Mark 8:32 in English
Mark 8:32 · Berean Standard Bible
He spoke this message quite frankly, and Peter took Him aside and began to rebuke Him.
Context
30Ṣùgbọ́n Jesu kìlọ̀ fún wọn, kí wọn má sọ èyí fún ẹnikẹ́ni. 31Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn, pé, Ọmọ Ènìyàn kò le ṣàìmá jìyà ohun púpọ̀, a ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀ láti ọwọ́ àwọn àgbàgbà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin, a ó sì pa á, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta yóò sì jíǹde. 32Jesu bá wọn sọ̀rọ̀ yìí, láìfi ohunkóhun pamọ́ fún wọn, ṣùgbọ́n Peteru pe Jesu sẹ́yìn, ó sì bẹ̀rẹ̀ si bá a wí. 33Jesu yípadà, ó wo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Ó sì wí fún Peteru pẹ̀lú ìtara pé, “Kúrò lẹ́yìn mi Satani, nítorí ìwọ kò ro ohun tí Ọlọ́run bí kò ṣe ohun tí ènìyàn.” 34Nígbà náà ni Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ènìyàn láti bá wọn sọ̀rọ̀, ó wí fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó si gbé àgbélébùú rẹ̀, kí ó si máa tọ̀ mi lẹ́yìn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.