Native Bible

Mark 6:46 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́yìn náà, ó lọ sórí òkè láti lọ gbàdúrà.

Mark 6:46 in English

Mark 6:46 · Berean Standard Bible

After bidding them farewell, He went up on the mountain to pray.

Context

44Àwọn tí ó sì jẹ́ àkàrà náà tó ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin. 45Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn èyí, Jesu pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti padà sínú ọkọ̀ kí wọn sì ṣáájú rékọjá sí Betisaida. Níbẹ̀ ni òun yóò ti wà pẹ̀lú wọn láìpẹ́. Nítorí òun fúnra a rẹ̀ yóò dúró sẹ́yìn láti rí i pé àwọn ènìyàn túká lọ ilé wọn. 46Lẹ́yìn náà, ó lọ sórí òkè láti lọ gbàdúrà. 47Nígbà tí ó di alẹ́, ọkọ̀ wà láàrín Òkun, òun nìkan sì wà lórí ilẹ̀. 48Ó rí i wí pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wà nínú wàhálà púpọ̀ ní wíwa ọkọ̀ náà nítorí ti ìjì líle ṣe ọwọ́ òdì sí wọn, nígbà tí ó sì dì ìwọ̀n ìṣọ́ kẹrin òru, ó tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi Òkun, òun sì fẹ́ ré wọn kọjá,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.