Native Bible

Mark 6:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí èyí, ọba rán ẹ̀ṣọ́ kan, ó fi àṣẹ fún un pé, kí ó gbé orí Johanu wá. Ọkùnrin náà sì lọ, ó bẹ́ Johanu lórí nínú túbú.

Mark 6:27 in English

Mark 6:27 · Berean Standard Bible

So without delay, the king commanded that John’s head be brought in. He sent an executioner, who went and beheaded him in the prison.

Context

25Ọmọbìnrin yìí sáré padà wá sọ́dọ̀ Herodu ọba. Ó sì wí fún un pé, “Mo ń fẹ́ orí Johanu Onítẹ̀bọmi nísinsin yìí nínú àwopọ̀kọ́.” 26Inú ọba sì bàjẹ́ gidigidi, ṣùgbọ́n nítorí àwọn ìbúra rẹ, àti nítorí àwọn tí ó bá a jókòó pọ̀, kò sì fẹ́ kọ̀ fún un. 27Nítorí èyí, ọba rán ẹ̀ṣọ́ kan, ó fi àṣẹ fún un pé, kí ó gbé orí Johanu wá. Ọkùnrin náà sì lọ, ó bẹ́ Johanu lórí nínú túbú. 28Ó sì gbé orí Johanu wa nínú àwopọ̀kọ́. Ó sì gbé e fún ọmọbìnrin náà. Òun sì gbé e tọ ìyá rẹ̀ lọ. 29Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu gbọ́, wọ́n wá gbé òkú rẹ̀, wọ́n sì lọ tẹ́ ẹ sínú ibojì.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.