Native Bible

Mark 6:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó jáde lọ sọ fún ìyá rẹ̀ pé, “Kí ní kí ń béèrè?” Ó dáhùn pé, “Orí Johanu Onítẹ̀bọmi.”

Mark 6:24 in English

Mark 6:24 · Berean Standard Bible

Then she went out and asked her mother, “What should I request?” And her mother answered, “The head of John the Baptist.”

Context

22Nígbà náà, ni ọmọbìnrin Herodia wọlé láti jó. Inú Herodu àti àwọn àlejò rẹ̀ dùn tó bẹ́ẹ̀. Ọba sọ fún ọmọbìnrin náà pé, “Béèrè ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́ lọ́wọ́ mi, èmi ó sì fi fún ọ.” 23Ó sì búra fún un wí pé, “Ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́, ìbá à ṣe ìdajì ìjọba mi ni, èmi yóò fi fún ọ.” 24Ó jáde lọ sọ fún ìyá rẹ̀ pé, “Kí ní kí ń béèrè?” Ó dáhùn pé, “Orí Johanu Onítẹ̀bọmi.” 25Ọmọbìnrin yìí sáré padà wá sọ́dọ̀ Herodu ọba. Ó sì wí fún un pé, “Mo ń fẹ́ orí Johanu Onítẹ̀bọmi nísinsin yìí nínú àwopọ̀kọ́.” 26Inú ọba sì bàjẹ́ gidigidi, ṣùgbọ́n nítorí àwọn ìbúra rẹ, àti nítorí àwọn tí ó bá a jókòó pọ̀, kò sì fẹ́ kọ̀ fún un.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.