Native Bible

Mark 5:41 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó gbá a ní ọwọ́ mú, ó sì wí pé, “Talita kuumi” (tí ó túmọ̀ sí “Ọmọdébìnrin, dìde dúró!”).

Mark 5:41 in English

Mark 5:41 · Berean Standard Bible

Taking her by the hand, Jesus said, “Talitha koum!” which means, “Little girl, I say to you, get up!”

Context

39Ó wọ inú ilé lọ, o sì bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, ó béèrè pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń sọkún tí ẹ sì ń pohùnréré ẹkún? Ọmọbìnrin náà kò kú, ó sùn lásán ni.” 40Wọ́n sì fi í rẹ́rìn-ín. Ṣùgbọ́n ó sọ fún gbogbo wọn láti bọ́ síta, ó mú baba àti ìyá ọmọ náà, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mẹ́ta. Ó sì wọ inú yàrá tí ọmọbìnrin náà gbé dùbúlẹ̀ sí. 41Ó gbá a ní ọwọ́ mú, ó sì wí pé, “Talita kuumi” (tí ó túmọ̀ sí “Ọmọdébìnrin, dìde dúró!”). 42Lẹ́sẹ̀kan náà, ọmọbìnrin náà sì dìde. Ó sì ń rìn, ẹ̀rù sì bà wọ́n, ẹnu sì ya àwọn òbí rẹ̀ gidigidi. 43Jesu sì kìlọ̀ fún wọn gidigidi pé kí wọn má ṣe sọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Ó sì wí fún wọn kí wọn fún ọmọbìnrin náà ní oúnjẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.