Marku 5:36
Mark 5:36 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n bi Jesu ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó wí fún Jairu pé, “Má bẹ̀rù, sá à gbàgbọ́ nìkan.”
Mark 5:36 in English
Mark 5:36 · Berean Standard Bible
But Jesus overheard * their conversation and said to Jairus, “Do not be afraid; just believe.”
Context
34Jesu sì wí fún un pé, “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá. Máa lọ ní àlàáfíà, ìwọ sì ti sàn nínú ààrùn rẹ.” 35Bí Jesu sì ti ń ba obìnrin náà sọ̀rọ̀, àwọn ìránṣẹ́ dé láti ilé Jairu olórí Sinagọgu wá, wọ́n wí fún un pé, ọmọbìnrin rẹ ti kú, àti pé kí wọn má ṣe yọ Jesu lẹ́nu láti wá, nítorí ó ti pẹ́ jù. 36Ṣùgbọ́n bi Jesu ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó wí fún Jairu pé, “Má bẹ̀rù, sá à gbàgbọ́ nìkan.” 37Nígbà náà, Jesu dá ọ̀pọ̀ ènìyàn náà dúró. Kò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tẹ̀lé òun lẹ́yìn lọ ilé Jairu, bí kò ṣe Peteru, Jakọbu àti Johanu arákùnrin Jakọbu. 38Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, Jesu rí i pé gbogbo nǹkan ti dàrú. Ilé kún fún àwọn tí ń sọkún, àti àwọn tí ń pohùnréré ẹkún.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.