Marku 4:22
Mark 4:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo ohun tí ó pamọ́ nísinsin yìí yóò hàn ní gbangba ní ọjọ́ kan, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀, bí kò ṣe pé kí ó le yọ sí gbangba.
Mark 4:22 in English
Mark 4:22 · Berean Standard Bible
For there is nothing hidden that will not be disclosed, and nothing concealed that will not be brought to light.
Context
20Ṣùgbọ́n àwọn tí ó bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, ní àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì gbà á lóòtítọ́, wọ́n sì mú èso púpọ̀ jáde fún Ọlọ́run ní ọgbọọgbọ̀n, ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún, gẹ́gẹ́ bí a ti gbìn ín sí ọkàn wọn.” 21Ó sì wí fún wọn pé, “A ha lè gbé fìtílà wá láti fi sábẹ́ òsùwọ̀n tàbí sábẹ́ àkéte? Rárá o, ki a ṣe pe a o gbé e ka orí ọ̀pá fìtílà? 22Gbogbo ohun tí ó pamọ́ nísinsin yìí yóò hàn ní gbangba ní ọjọ́ kan, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀, bí kò ṣe pé kí ó le yọ sí gbangba. 23Bí ẹnikẹ́ni bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́.” 24Ó sì tún tẹ̀síwájú pé, “Ẹ máa kíyèsi ohun tí ẹ bà gbọ́ dáradára, nítorí òsùwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ́n náà ni a ó fi wọ́n fún un yín àti jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.