Native Bible

Mark 4:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì wí fún wọn pé, “A ha lè gbé fìtílà wá láti fi sábẹ́ òsùwọ̀n tàbí sábẹ́ àkéte? Rárá o, ki a ṣe pe a o gbé e ka orí ọ̀pá fìtílà?

Mark 4:21 in English

Mark 4:21 · Berean Standard Bible

Jesus also said to them, “Does anyone bring in a lamp to put it under a basket or under a bed? Doesn’t he set it on a stand?

Context

19Ṣùgbọ́n láìpẹ́ jọjọ, àwọn adùn ayé àti inú dídùn, ọrọ̀ àti ìjàkadì fún àṣeyọrí àti ìfẹ́ àwọn ohun mèremère ayé, gba ọkàn wọn, wọ́n sì fún ọ̀rọ̀ náà pa ní ọkàn wọn. Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ aláìléso. 20Ṣùgbọ́n àwọn tí ó bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, ní àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì gbà á lóòtítọ́, wọ́n sì mú èso púpọ̀ jáde fún Ọlọ́run ní ọgbọọgbọ̀n, ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún, gẹ́gẹ́ bí a ti gbìn ín sí ọkàn wọn.” 21Ó sì wí fún wọn pé, “A ha lè gbé fìtílà wá láti fi sábẹ́ òsùwọ̀n tàbí sábẹ́ àkéte? Rárá o, ki a ṣe pe a o gbé e ka orí ọ̀pá fìtílà? 22Gbogbo ohun tí ó pamọ́ nísinsin yìí yóò hàn ní gbangba ní ọjọ́ kan, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀, bí kò ṣe pé kí ó le yọ sí gbangba. 23Bí ẹnikẹ́ni bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.