Marku 15:2
Mark 15:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Pilatu sì bi í léèrè, ó ni, “Ṣe ìwọ ni ọba àwọn Júù?” Jesu sì dáhùn pé, “Gẹ́gẹ́ bi ìwọ ti wí náà ni.”
Mark 15:2 in English
Mark 15:2 · Berean Standard Bible
So Pilate questioned Him, “Are You the King of the Jews?” “You have said so,” Jesus replied.
Context
1Ní kùtùkùtù òwúrọ̀, àwọn olórí àlùfáà, àwọn àgbàgbà, àwọn olùkọ́ òfin àti gbogbo àjọ ìgbìmọ̀ fi ẹnu kò lórí ohun tí wọn yóò ṣe. Wọ́n sì de Jesu, wọ́n mú un lọ, wọ́n sì fi lé Pilatu lọ́wọ́. 2Pilatu sì bi í léèrè, ó ni, “Ṣe ìwọ ni ọba àwọn Júù?”
Jesu sì dáhùn pé, “Gẹ́gẹ́ bi ìwọ ti wí náà ni.” 3Àwọn olórí àlùfáà fi ẹ̀sùn ohun púpọ̀ kàn án. 4Pilatu sì tún bi í léèrè pé, “Ṣe ìwọ kò dáhùn ni? Wo gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn ọ.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.