Native Bible

Mark 14:71 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni Peteru bẹ̀rẹ̀ sí í sẹ́ ó sì ń búra, ó ni, “N kò mọ ẹni ti ẹ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yí rí!”

Mark 14:71 in English

Mark 14:71 · Berean Standard Bible

But he began to curse and swear, “I do not know this man of whom you speak!”

Context

69Ọmọbìnrin náà sì tún rí Peteru. Ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sí wí fún àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀. Ó ní, “Ọkùnrin yìí gan an jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu.” 70Ṣùgbọ́n Peteru tún sẹ́. Nígbà tí ó sí túnṣe díẹ̀ sí i, àwọn tí wọ́n dúró lẹ́gbẹ́ Peteru wá wí fún un pé, “Lóòótọ́ ni, ọ̀kan ní ara wọn ni ìwọ í ṣe. Nítorí ará Galili ni ìwọ, èdè rẹ sì jọ bẹ́ẹ̀.” 71Nígbà náà ni Peteru bẹ̀rẹ̀ sí í sẹ́ ó sì ń búra, ó ni, “N kò mọ ẹni ti ẹ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yí rí!” 72Lójúkan náà tí àkùkọ yìí kọ lẹ́ẹ̀kejì Peteru rántí ọ̀rọ̀ Jesu fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ lẹ́ẹ̀méjì, ìwọ yóò sẹ́ mí nígbà mẹ́ta.” Ó sì rẹ̀ ẹ́ láti inú ọkàn wá, ó sì sọkún.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.