Native Bible

Mark 14:51 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọ̀dọ́mọkùnrin kan sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn tí ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ bo ìhòhò rẹ̀ àwọn ọmọ-ogun gbìyànjú láti mú òun náà.

Mark 14:51 in English

Mark 14:51 · Berean Standard Bible

One young man who had been following Jesus was wearing a linen cloth around his body. They caught hold of him,

Context

49Ojoojúmọ́ ni èmi wà pẹ̀lú yín ní tẹmpili, tí mo ń kọ́ni; ẹ kò mú mi. Ṣùgbọ́n eléyìí ṣẹlẹ̀, kí ohun tí ìwé Mímọ́ wí lè ṣẹ.” 50Ní àkókò yìí, gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti fi í sílẹ̀, wọ́n sálọ. 51Ọ̀dọ́mọkùnrin kan sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn tí ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ bo ìhòhò rẹ̀ àwọn ọmọ-ogun gbìyànjú láti mú òun náà. 52Ó sì fi aṣọ funfun náà sílẹ̀ fún wọn, ó sì sálọ ní ìhòhò. 53Wọ́n mú Jesu lọ sí ilé olórí àlùfáà, gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù àti àwọn olùkọ́ òfin péjọ síbẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.