Native Bible

Mark 14:43 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ó sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, lójú ẹsẹ̀ náà ni Judasi ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá dé pẹ̀lú. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti idà àti kùmọ̀ lọ́wọ́, àwọn olórí àlùfáà, àwọn olùkọ́ òfin àti àwọn àgbàgbà Júù ni ó rán wọn wá.

Mark 14:43 in English

Mark 14:43 · Berean Standard Bible

While Jesus was still speaking, Judas, one of the Twelve, arrived, accompanied by a crowd armed with swords and clubs, sent from the chief priests, scribes, and elders.

Context

41Ó sì wá nígbà kẹta, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa sùn kí ẹ sì máa sinmi ó tó bẹ́ẹ̀, wákàtí náà ti dé, wò ó, a fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́. 42Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a máa lọ. Ẹ wò ó, ẹni tí yóò fi mí hàn wà ní tòsí!” 43Bí ó sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, lójú ẹsẹ̀ náà ni Judasi ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá dé pẹ̀lú. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti idà àti kùmọ̀ lọ́wọ́, àwọn olórí àlùfáà, àwọn olùkọ́ òfin àti àwọn àgbàgbà Júù ni ó rán wọn wá. 44Judasi tí fi àmì fún wọn wí pe, “Ẹni tí mo bá fi ẹnu kò lẹ́nu nínú wọn, òun ní Jesu, ẹ mú un.” 45Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu, Judasi lọ sì ọ̀dọ̀ rẹ̀ tààrà, ó wí pé, “Rabbi!” Ó sì fi ẹnu kò Jesu lẹ́nu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.