Native Bible

Mark 14:42 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a máa lọ. Ẹ wò ó, ẹni tí yóò fi mí hàn wà ní tòsí!”

Mark 14:42 in English

Mark 14:42 · Berean Standard Bible

Rise, let us go. See, My betrayer is approaching!”

Context

40Nígbà tí ó sì tún padà dé, ó bá wọn wọ́n ń sùn, nítorí pé ojú wọn kún fún oorun. Wọn kò sì mọ irú èsì tí wọn ìbá fún un. 41Ó sì wá nígbà kẹta, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa sùn kí ẹ sì máa sinmi ó tó bẹ́ẹ̀, wákàtí náà ti dé, wò ó, a fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́. 42Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a máa lọ. Ẹ wò ó, ẹni tí yóò fi mí hàn wà ní tòsí!” 43Bí ó sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, lójú ẹsẹ̀ náà ni Judasi ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá dé pẹ̀lú. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti idà àti kùmọ̀ lọ́wọ́, àwọn olórí àlùfáà, àwọn olùkọ́ òfin àti àwọn àgbàgbà Júù ni ó rán wọn wá. 44Judasi tí fi àmì fún wọn wí pe, “Ẹni tí mo bá fi ẹnu kò lẹ́nu nínú wọn, òun ní Jesu, ẹ mú un.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.