Native Bible

Mark 14:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó rán méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sínú ìlú, ọkùnrin kan tó ru ìkòkò omi yóò pàdé yín, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

Mark 14:13 in English

Mark 14:13 · Berean Standard Bible

So He sent two of His disciples and told them, “Go into the city, and a man carrying a jug of water will meet you. Follow him,

Context

11Inú wọn dùn láti gbọ́ èyí, wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì ṣe ìlérí láti fún un ní owó. Nítorí náà ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ àkókò tí ó rọrùn tí òun yóò fi Jesu lé wọn lọ́wọ́. 12Ní ọjọ́ kìn-ín-ní àjọ̀dún ìrékọjá tí í ṣe ọjọ́ tí wọ́n máa ń pa ẹran àgùntàn fún ìrúbọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu bi í léèrè pé, “Níbo ni ìwọ fẹ́ kí a lọ pèsè sílẹ̀ tí ìwọ yóò ti jẹ àsè ìrékọjá?” 13Ó rán méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sínú ìlú, ọkùnrin kan tó ru ìkòkò omi yóò pàdé yín, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. 14Ilé tí ọkùnrin náà bá wọ̀, kí ẹ wí fún baálé náà pé, ‘Olùkọ́ rán wa pé, níbo ni gbàngàn àpèjẹ náà gbé wa, níbi tí èmi yóò gbé jẹ àsè ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi?’ 15Òun yóò sì mú un yín lọ sí gbàngàn ńlá kan lókè ilé náà, tí a ti ṣe lọ́sọ́. Níbẹ̀ ni kí ẹ pèsè sílẹ̀ dè wá.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.