Marku 13:20
Mark 13:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Àfi tí Olúwa bá gé àkókò ìjìyà náà kúrú, ẹyọ ẹ̀mí kan ní ayé kì yóò là. Ṣùgbọ́n nítorí àwọn tí Ọlọ́run yàn, ni yóò ṣe dín àwọn ọjọ́ náà kù.
Mark 13:20 in English
Mark 13:20 · Berean Standard Bible
If the Lord had not cut short those days, nobody would be saved. But for the sake of the elect, whom He has chosen, He has cut them short.
Context
18Kí ẹ sì máa gbàdúrà pé èyí ṣẹlẹ̀ ní àkókò òtútù. 19Nítorí ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì yóò jẹ́ àkókò ìpọ́njú, irú èyí tí kò ì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá Ọlọ́run. Irú rẹ̀ kò sì ni ṣẹlẹ̀ mọ́. 20“Àfi tí Olúwa bá gé àkókò ìjìyà náà kúrú, ẹyọ ẹ̀mí kan ní ayé kì yóò là. Ṣùgbọ́n nítorí àwọn tí Ọlọ́run yàn, ni yóò ṣe dín àwọn ọjọ́ náà kù. 21Nígbà náà, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún un yín pé, ‘Ẹ wò ó, Kristi wa níbi yìí!’ tàbí, sọ fún un yín pé, ‘Ẹ wò ó, ó wà lọ́hùn ún nì!’ Ẹ má ṣe gbà wọ́n gbọ́. 22Nítorí àwọn èké Kristi àti àwọn wòlíì èké ni yóò wá, wọn yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu tí yóò tan ènìyàn jẹ hàn. Bí ó bá ṣe é ṣe, wọn yóò tan àwọn àyànfẹ́ pàápàá jẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.