Native Bible

Mark 12:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jesu dáhùn ó wí fún wọn pé, “Kì í há ṣe nítorí èyí ni ẹ ṣe ṣìnà, pé ẹ̀yin kò mọ ìwé Mímọ́, tàbí agbára Ọlọ́run.

Mark 12:24 in English

Mark 12:24 · Berean Standard Bible

Jesus said to them, “Aren’t you mistaken, because you do not know the Scriptures or the power of God?

Context

22Àwọn méjèèje sì ṣú u lópó, wọn kò sì fi ọmọ sílẹ̀. Ní ìkẹyìn gbogbo wọn, obìnrin náà kú pẹ̀lú. 23Ǹjẹ́ ní àjíǹde, nígbà tí wọ́n bá jíǹde, aya ta ni yóò ha ṣe nínú wọn? Àwọn méjèèje ni ó sá ni ní aya?” 24Jesu dáhùn ó wí fún wọn pé, “Kì í há ṣe nítorí èyí ni ẹ ṣe ṣìnà, pé ẹ̀yin kò mọ ìwé Mímọ́, tàbí agbára Ọlọ́run. 25Nítorí pé, nígbà tí àwọn arákùnrin méje yìí àti obìnrin náà bá jí dìde nínú òkú, a kò ní ṣe ìgbéyàwó fún wọn. Wọn yóò dàbí àwọn angẹli tí ń bẹ ní ọ̀run. 26Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa bóyá àjíǹde yóò wà. Àbí ẹ̀yin kò ì tí ka ìwé Eksodu, nípa Mose àti pápá tí ń jó? Ọlọ́run sọ fún Mose pé, ‘Èmi ni Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki àti Ọlọ́run Jakọbu.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.