Marku 12:22
Mark 12:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn méjèèje sì ṣú u lópó, wọn kò sì fi ọmọ sílẹ̀. Ní ìkẹyìn gbogbo wọn, obìnrin náà kú pẹ̀lú.
Mark 12:22 in English
Mark 12:22 · Berean Standard Bible
In this way, none of the seven left any children. And last of all, the woman died.
Context
20Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan wà, èyí tí ó dàgbà jùlọ gbéyàwó, ó sì kú ní àìlọ́mọ. 21Arákùnrin rẹ̀ kejì ṣú obìnrin tí ó fi sílẹ̀ lópó, láìpẹ́, òun pẹ̀lú tún kú láìbímọ. Arákùnrin kẹta tó ṣú obìnrin yìí lópó tún kú bákan náà láìbímọ. 22Àwọn méjèèje sì ṣú u lópó, wọn kò sì fi ọmọ sílẹ̀. Ní ìkẹyìn gbogbo wọn, obìnrin náà kú pẹ̀lú. 23Ǹjẹ́ ní àjíǹde, nígbà tí wọ́n bá jíǹde, aya ta ni yóò ha ṣe nínú wọn? Àwọn méjèèje ni ó sá ni ní aya?” 24Jesu dáhùn ó wí fún wọn pé, “Kì í há ṣe nítorí èyí ni ẹ ṣe ṣìnà, pé ẹ̀yin kò mọ ìwé Mímọ́, tàbí agbára Ọlọ́run.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.