Marku 11:21
Mark 11:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Peteru rántí pé Jesu ti bá igi náà wí. Nígbà náà ni ó sọ fún Jesu pé, “Rabbi, wò ó! Igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ìwọ fi bú ti gbẹ!”
Mark 11:21 in English
Mark 11:21 · Berean Standard Bible
Peter remembered it and said, “Look, Rabbi! The fig tree You cursed has withered.”
Context
19Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, bí ìṣe wọn, Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jáde kúrò ní ìlú Jerusalẹmu. 20Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti ń kọjá lọ, wọ́n rí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí Jesu fi bú. Wọ́n rí i pé ó ti gbẹ tigbòǹgbò tigbòǹgbò. 21Peteru rántí pé Jesu ti bá igi náà wí. Nígbà náà ni ó sọ fún Jesu pé, “Rabbi, wò ó! Igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ìwọ fi bú ti gbẹ!” 22Jesu sì dáhùn pé, “Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. 23Lóòótọ́ ni mò wí fún un yín, bí ẹnikẹ́ni bá wí fún òkè ‘Ṣídìí, gbé ara rẹ sọ sínú Òkun,’ ti kò sì ṣe iyèméjì nínú ọkàn rẹ̀ ṣùgbọ́n tí ó gbàgbọ́ pé ohun tí òun wí yóò ṣẹ, yóò rí bẹ́ẹ̀ fún un.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.