Marku 10:44
Mark 10:44 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ di aṣáájú nínú yín gbọdọ̀ ṣe ìránṣẹ́ gbogbo yín.
Mark 10:44 in English
Mark 10:44 · Berean Standard Bible
and whoever wants to be first must be the slave of all.
Context
42Nítorí ìdí èyí, Jesu pè wọ́n sọ́dọ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé, àwọn ọba àti àwọn kèfèrí ń lo agbára lórí àwọn ènìyàn. 43Ṣùgbọ́n láàrín yín ko gbọdọ̀ ri bẹ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ di olórí nínú yín gbọdọ̀ ṣe ìránṣẹ́. 44Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ di aṣáájú nínú yín gbọdọ̀ ṣe ìránṣẹ́ gbogbo yín. 45Nítorí, Èmi, Ọmọ Ènìyàn kò wá sí ayé kí ẹ lè ṣe ìránṣẹ́ fún mi, ṣùgbọ́n láti lè ṣe ìránṣẹ́ fun àwọn ẹlòmíràn, àti láti fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà ọ̀pọ̀ ènìyàn.” 46Wọ́n dé Jeriko, bí Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ènìyàn ti fẹ́ kúrò ní ìlú Jeriko, ọkùnrin afọ́jú kan, Bartimeu, ọmọ Timeu jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà ó ń ṣagbe.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.