Marku 10:41
Mark 10:41 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàá ìyókù gbọ́ ohun tí Jakọbu àti Johanu béèrè, wọ́n bínú.
Mark 10:41 in English
Mark 10:41 · Berean Standard Bible
When the ten heard about this, they became indignant with James and John.
Context
39Àwọn méjèèjì dáhùn pé, “Àwa pẹ̀lú lè ṣe bẹ́ẹ̀.”
Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni ẹ̀yin ó mu ago ti èmi yóò mu, àti bamitiisi tí a sí bamitiisi mi ni a ó fi bamitiisi yín, 40ṣùgbọ́n láti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi àti ní ọwọ́ òsì mi kì ì ṣe ti èmi láti fi fún ni: bí kò ṣe fún àwọn ẹni tí a ti pèsè rẹ̀ sílẹ̀ fún.” 41Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàá ìyókù gbọ́ ohun tí Jakọbu àti Johanu béèrè, wọ́n bínú. 42Nítorí ìdí èyí, Jesu pè wọ́n sọ́dọ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé, àwọn ọba àti àwọn kèfèrí ń lo agbára lórí àwọn ènìyàn. 43Ṣùgbọ́n láàrín yín ko gbọdọ̀ ri bẹ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ di olórí nínú yín gbọdọ̀ ṣe ìránṣẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.