Marku 10:40
Mark 10:40 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
ṣùgbọ́n láti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi àti ní ọwọ́ òsì mi kì ì ṣe ti èmi láti fi fún ni: bí kò ṣe fún àwọn ẹni tí a ti pèsè rẹ̀ sílẹ̀ fún.”
Mark 10:40 in English
Mark 10:40 · Berean Standard Bible
But to sit at My right or left is not Mine to grant. These seats belong to those for whom * they have been prepared.”
Context
38Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò mọ ohun tí ẹ̀ ń béèrè! Ṣe ẹ lè mu nínú ago kíkorò tí èmi ó mú tàbí a lè bamitiisi yín pẹ̀lú irú ì bamitiisi ìjìyà tí a ó fi bamitiisi mi?” 39Àwọn méjèèjì dáhùn pé, “Àwa pẹ̀lú lè ṣe bẹ́ẹ̀.”
Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni ẹ̀yin ó mu ago ti èmi yóò mu, àti bamitiisi tí a sí bamitiisi mi ni a ó fi bamitiisi yín, 40ṣùgbọ́n láti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi àti ní ọwọ́ òsì mi kì ì ṣe ti èmi láti fi fún ni: bí kò ṣe fún àwọn ẹni tí a ti pèsè rẹ̀ sílẹ̀ fún.” 41Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàá ìyókù gbọ́ ohun tí Jakọbu àti Johanu béèrè, wọ́n bínú. 42Nítorí ìdí èyí, Jesu pè wọ́n sọ́dọ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé, àwọn ọba àti àwọn kèfèrí ń lo agbára lórí àwọn ènìyàn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.