Native Bible

Mark 1:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jesu sì ké sí wọn wí pé, “Ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn. Èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.”

Mark 1:17 in English

Mark 1:17 · Berean Standard Bible

“Come, follow Me,” Jesus said, “and I will make you fishers of men.”

Context

15Ó sì kéde wí pé, “Àkókò náà dé wàyí, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀. Ẹ yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì gba ìyìnrere yìí gbọ́.” 16Ní ọjọ́ kan, bí Jesu ti ń rìn létí Òkun Galili, Ó rí Simoni àti Anderu arákùnrin rẹ̀, wọ́n ń fi àwọ̀n wọn pẹja torí pé apẹja ni wọ́n. 17Jesu sì ké sí wọn wí pé, “Ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn. Èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.” 18Ní kánkán wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ Ọ́ lẹ́yìn. 19Bí Ó sì ti rìn síwájú díẹ̀, ní etí Òkun, Ó rí Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu arákùnrin rẹ̀ nínú ọkọ̀, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.