Native Bible

Mark 1:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọjọ́ kan, bí Jesu ti ń rìn létí Òkun Galili, Ó rí Simoni àti Anderu arákùnrin rẹ̀, wọ́n ń fi àwọ̀n wọn pẹja torí pé apẹja ni wọ́n.

Mark 1:16 in English

Mark 1:16 · Berean Standard Bible

As Jesus was walking beside the Sea of Galilee, He saw Simon and his brother Andrew. They were casting a net into the sea, for they were fishermen.

Context

14Lẹ́yìn ìgbà tí ọba Herodu ti fi Johanu sínú ẹ̀wọ̀n tan, Jesu lọ sí Galili, ó ń wàásù ìyìnrere ti ìjọba Ọlọ́run. 15Ó sì kéde wí pé, “Àkókò náà dé wàyí, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀. Ẹ yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì gba ìyìnrere yìí gbọ́.” 16Ní ọjọ́ kan, bí Jesu ti ń rìn létí Òkun Galili, Ó rí Simoni àti Anderu arákùnrin rẹ̀, wọ́n ń fi àwọ̀n wọn pẹja torí pé apẹja ni wọ́n. 17Jesu sì ké sí wọn wí pé, “Ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn. Èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.” 18Ní kánkán wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ Ọ́ lẹ́yìn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.