Mika 7:4
Micah 7:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹni tí ó sàn jùlọ nínú wọn sì dàbí ẹ̀gún, ẹni tí ó jẹ́ olódodo jùlọ burú ju ẹ̀gún ọgbà lọ. Ọjọ́ àwọn olùṣọ́ rẹ̀ ti dé, àti ọjọ́ tí Ọlọ́run bẹ̀ ọ́ wò. Nísinsin yìí ní àkókò ìdààmú wọn.
Micah 7:4 in English
Micah 7:4 · Berean Standard Bible
The best of them is like a brier; the most upright is sharper than a hedge of thorns. The day for your watchmen has come, the day of your visitation.* Now is the time of their confusion.
Context
2Àwọn olódodo sì ti kúrò ní ilẹ̀ náà,
kò sì ṣí ẹnìkan tí ó ṣẹ́kù tí ó jọ olóòtítọ́;
gbogbo wọn sì ń purọ́ ní dídúró nítorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀,
olúkúlùkù wọ́n sì ń fi àwọ̀n de arákùnrin rẹ̀. 3Ọwọ́ wọn méjèèjì ti múra tán láti ṣe búburú;
àwọn alákòóso ń béèrè fún ẹ̀bùn,
àwọn onídàájọ́ sì ń gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀
alágbára sì ń pàṣẹ ohun tí wọ́n fẹ́,
gbogbo wọn sì jùmọ̀ ń dìtẹ̀. 4Ẹni tí ó sàn jùlọ nínú wọn sì dàbí ẹ̀gún,
ẹni tí ó jẹ́ olódodo jùlọ burú ju ẹ̀gún ọgbà lọ.
Ọjọ́ àwọn olùṣọ́ rẹ̀ ti dé,
àti ọjọ́ tí Ọlọ́run bẹ̀ ọ́ wò.
Nísinsin yìí ní àkókò ìdààmú wọn. 5Ẹ má ṣe gba ọ̀rẹ́ kan gbọ́;
ẹ má sì ṣe gbẹ́kẹ̀lé amọ̀nà kankan.
Pa ìlẹ̀kùn ẹnu rẹ fún ẹni
tí ó sùn ní oókan àyà rẹ. 6Nítorí tí ọmọkùnrin kò bọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀,
ọmọbìnrin sì dìde sí ìyá rẹ̀,
aya ọmọ sí ìyá ọkọ rẹ̀,
ọ̀tá olúkúlùkù ni àwọn ará ilé rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.