Mika 7:1
Micah 7:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ègbé ni fún mi! Nítorí èmi sì dàbí ẹni tí ń kó èso ẹ̀ẹ̀rùn jọ, ìpèsè ọgbà àjàrà; kò sì ṣí odidi àjàrà kankan láti jẹ, kò sì ṣí àkọ́so ọ̀pọ̀tọ́ nítorí tí ebi ń pa mí.
Micah 7:1 in English
Micah 7:1 · Berean Standard Bible
Woe is me! For I am like one gathering summer fruit at the gleaning of the vineyard; there is no cluster to eat, no early fig that I crave.
Context
1Ègbé ni fún mi!
Nítorí èmi sì dàbí ẹni tí ń kó èso ẹ̀ẹ̀rùn jọ,
ìpèsè ọgbà àjàrà;
kò sì ṣí odidi àjàrà kankan láti jẹ,
kò sì ṣí àkọ́so ọ̀pọ̀tọ́ nítorí tí ebi ń pa mí. 2Àwọn olódodo sì ti kúrò ní ilẹ̀ náà,
kò sì ṣí ẹnìkan tí ó ṣẹ́kù tí ó jọ olóòtítọ́;
gbogbo wọn sì ń purọ́ ní dídúró nítorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀,
olúkúlùkù wọ́n sì ń fi àwọ̀n de arákùnrin rẹ̀. 3Ọwọ́ wọn méjèèjì ti múra tán láti ṣe búburú;
àwọn alákòóso ń béèrè fún ẹ̀bùn,
àwọn onídàájọ́ sì ń gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀
alágbára sì ń pàṣẹ ohun tí wọ́n fẹ́,
gbogbo wọn sì jùmọ̀ ń dìtẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.