Native Bible

Micah 2:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ègbé ni fún àwọn tí ń gbèrò àìṣedéédéé tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ ibi lórí ibùsùn wọn! Nígbà tí ojúmọ́ bá mọ́, wọn yóò gbé e jáde nítorí ó wà ní agbára wọn láti ṣe é.

Micah 2:1 in English

Micah 2:1 · Berean Standard Bible

Woe to those who devise iniquity and plot evil on their beds! At morning’s light they accomplish it because the power is in their hands.

Context

1Ègbé ni fún àwọn tí ń gbèrò àìṣedéédéé tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ ibi lórí ibùsùn wọn! Nígbà tí ojúmọ́ bá mọ́, wọn yóò gbé e jáde nítorí ó wà ní agbára wọn láti ṣe é. 2Wọ́n sì ń ṣe ojúkòkòrò oko, wọ́n sì fi agbára wọn gbà wọ́n, àti àwọn ilé, wọ́n sì gbà wọ́n. Wọ́n sì ni ènìyàn àti ilẹ̀ rẹ̀ lára àní ènìyàn àti ohun ìní rẹ̀. 3Nítorí náà, Olúwa wí pé: “Èmi ń gbèrò ibi sí àwọn ìdílé wọ̀nyí, nínú èyí tí wọn kì yóò le è gba ara wọn là. Ìwọ kì yóò sì lè máa rìn ní ìgbéraga mọ́, nítorí yóò jẹ́ àkókò ibi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.